Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ṣé Ẹ Ti Múra Tán Láti Ṣe Ìrìbọmi?
“Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?”—LÚÙKÙ 14:28.
ORIN: 120, 64
Torí àwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣèrìbọmi la ṣe kọ àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e
1, 2. (a) Kí ló ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run láyọ̀ lónìí? (b) Báwo làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí?
ALÀGBÀ kan sọ fún ọmọ ọdún méjìlá kan tó ń jẹ́ Christopher pé “àtikékeré ni mo ti mọ̀ ẹ́, inú mi sì dùn nígbà tí mo gbọ́ pé o fẹ́ ṣèrìbọmi. Àmọ́, mo fẹ́ bi ẹ́ ní ìbéèrè kan, ‘Kí nìdí tó o fi fẹ́ ṣèrìbọmi?’” Ó nídìí tí alàgbà yẹn fi béèrè ìbéèrè yẹn. Inú wa ń dùn gan-an bá a ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún. (Oníwàásù 12:1) Síbẹ̀, ó yẹ káwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí àtàwọn alàgbà rí i dájú pé àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìpinnu yìí fúnra wọn, wọ́n sì mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣèrìbọmi.
2 A ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì pé ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi jẹ́ fún Kristẹni kan. Ìgbésí ayé tuntun yìí máa mú ká rí ìbùkún Jèhófà, àmọ́ ó máa mú Òwe 10:22; 1 Pétérù 5:8) Ìdí nìyẹn tó fi pọn dandan pé káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni rí i dájú pé àwọn ń wáyè láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè mọ ohun tó túmọ̀ sí ní ti gidi láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Tí òbí àwọn ọmọ kan kì í bá ṣe Kristẹni, àwọn alàgbà ìjọ á fìfẹ́ ran irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. (Ka Lúùkù 14:27-30.) Bó ṣe jẹ́ pé ẹni bá fẹ́ kọ́lé máa ń gbéṣirò lé e, bákan náà, àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ kí wọ́n tó ṣèrìbọmi, kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà “dé òpin.” (Mátíù 24:13) Kí ló máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti pinnu pé Jèhófà làwọn á máa sìn títí láé? Ẹ máa fọkàn bá ìjíròrò yìí lọ.
kí Sátánì ṣàtakò sí wa. (3. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ Jésù àti Pétérù kọ́ wa nípa bí ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó? (Mátíù 28:19, 20; 1 Pétérù 3:21) (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò, kí sì nìdí?
3 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ṣó wu ìwọ náà pé kó o ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa lo fẹ́ ṣe yẹn! Kò sí ohun tó dáa tó kéèyàn ṣèrìbọmi, kó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi, ohun tó sì yẹ kí gbogbo àwọn tó bá máa là á já nígbà ìpọ́njú ńlá náà ṣe nìyẹn. (Mátíù 28:19, 20; 1 Pétérù 3:21) Tó o bá ṣèrìbọmi, ṣe lò ń ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá máa sìn ín títí láé. Ó sì dájú pé wàá fẹ́ mú ìlérí yẹn ṣẹ. Torí náà àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ kó o mọ̀ bóyá òótọ́ lo ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi: (1) Ṣé mo ti dàgbà dénú tó láti pinnu pé màá ṣèrìbọmi? (2) Ṣó wá látọkàn mi pé kí n ṣèrìbọmi? (3) Ṣé mo mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè yìí.
ṢÓ O TI DÀGBÀ DÉNÚ TÓ?
4, 5. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe àwọn àgbàlagbà nìkan ni ìrìbọmi wà fún? (b) Tá a bá sọ pé Kristẹni kan dàgbà dénú, kí ló túmọ̀ sí?
4 Bíbélì ò sọ pé àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn tó ti pé iye ọdún kan pàtó ló gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. Ìwé Òwe 20:11 sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” Torí náà, àwọn ọmọdé pàápàá lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe ohun tó tọ́ kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá wọn. Ó ti wá ṣe kedere pé bí ọ̀dọ́ kan bá ti gbọ́njú tó sì ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó ṣèrìbọmi.—Òwe 20:7.
5 Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn dàgbà dénú? Ohun kan ni pé béèyàn ṣe tó tàbí ọjọ́ orí ẹni kọ́ la fi ń màgbà. Kódà, Hébérù 5:14) Torí náà, ẹni tó dàgbà dénú ni ẹni tó gbọ́n tó láti ṣèpinnu, tó mọ ohun tó tọ́, tó sì ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé ohun tó tọ́ lòun á máa ṣe. Kì í ṣẹni téèyàn lè tì ṣe ohun tí kò tọ́, kò sì dìgbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún un kó tó ṣe ohun tó tọ́. Ó yẹ kí ọkàn èèyàn balẹ̀ pé ohun tó tọ́ ni ọ̀dọ́ kan tó ti ṣèrìbọmi máa ṣe kódà tí àwọn òbí ẹ̀ tàbí àwọn àgbàlagbà míì ò bá tiẹ̀ sí níbẹ̀.—Fi wé Fílípì 2:12.
Bíbélì sọ pé àwọn tó dàgbà dénú ti kọ́ “agbára ìwòye” wọn kí wọ́n lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (6, 7. (a) Ìṣòro wo ni Dáníẹ́lì ní nígbà tó wà nílùú Bábílónì? (b) Kí ni Dáníẹ́lì ṣe tó fi hàn pé ó dàgbà dénú?
6 Ǹjẹ́ ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ lè fi hàn pé òótọ́ lòun ti gbọ́n tó láti dá ṣèpinnu? Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì. Ó ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì má tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tí wọ́n mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lọ sílùú Bábílónì. Bó ṣe bára ẹ̀ láàárín àwọn tí kò mọ òfin Ọlọ́run nìyẹn. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká fojú ṣùnnùkùn wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì. Ó bára rẹ̀ nípò pàtàkì nílùú Bábílónì. Ó wà lára àwọn ọ̀dọ́ kéréje tí wọ́n dìídì yàn láti máa ṣiṣẹ́ fún ọba. (Dáníẹ́lì 1:3-5, 13) Ó jọ pé tí Dáníẹ́lì bá tiẹ̀ wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì pàápàá kò ní lè dé irú ipò tó wà yẹn.
7 Kí ni Dáníẹ́lì wá ṣe? Ṣó jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì yí irú ẹni tó jẹ́ pa dà tàbí kí wọ́n sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di ahẹrẹpẹ? Rárá, kò gba irú ẹ̀ láyè! Bíbélì sọ pé nígbà tí Dáníẹ́lì wà ní Bábílónì, ó pinnu Dáníẹ́lì 1:8) Ẹ ò rí i pé ohun tí Dáníẹ́lì ṣe yìí fi hàn pé ó ti dàgbà dénú lóòótọ́!
“ní ọkàn-àyà rẹ̀ pé òun kì yóò sọ ara òun di eléèérí,” pé òun ò ní ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìsìn èké. (8. Kí lo rí kọ́ lára Dáníẹ́lì?
8 Kí lo lè rí kọ́ lára Dáníẹ́lì? Ọ̀dọ́ kan tó dàgbà dénú ò ní máa ṣiyè méjì nípa ohun tó gbà gbọ́, kódà nígbà tí nǹkan bá le koko. Kò ní dà bí ọ̀gà tó máa ń gbé àwọ̀ ibi tó bá bá ara rẹ̀ wọ̀. Kò ní máa ṣe bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kó wá dé iléèwé kó máa ṣohun táyé ń fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe ohun tó tọ́ bí wọ́n bá dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò.—Ka Éfésù 4:14, 15.
9, 10. (a) Bí ọ̀dọ́ kan bá ń ronú nípa ohun tó ṣe nípa àwọn àdánwò kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dojú kọ, báwo nìyẹn ṣe lè ràn án lọ́wọ́? (b) Kí ni ìrìbọmi?
9 A kì í mọ̀ ọ́n rìn kórí má mì. Tọmọdé tàgbà wa ló máa ń ṣàṣìṣe. (Oníwàásù 7:20) Àmọ́, tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, á dáa kó o ronú jinlẹ̀ dáadáa kó o lè mọ̀ bóyá o ti ṣe tán láti ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Jèhófà. O lè bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà?’ Ronú nípa ohun tó o ṣe nígbà tẹ́nì kan dán ìgbàgbọ́ rẹ wò kẹ́yìn. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ẹ láti pinnu ohun tó yẹ kó o ṣe? Bí àpẹẹrẹ, Dáníẹ́lì ò gbéra ga torí ẹ̀bùn tó ní. Ìwọ náà ńkọ́? Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan bá gbà ẹ́ níyànjú pé kó o lo ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ tó o ní nínú ayé Sátánì? Bí ohun tó sọ yẹn bá mú kó wù ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe?—Éfésù 5:17.
10 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn? Ìdí ni pé wọ́n á jẹ́ kó o mọ̀ pé ìrìbọmi kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Ìrìbọmi ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ṣe ìlérí pàtàkì kan fún Jèhófà. O ṣèlérí pé wàá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wàá sì máa sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ. (Máàkù 12:30) Gbogbo ẹni tó ti ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ pinnu pé àwọn á mú ìlérí tí wọ́n ṣe fún Jèhófà ṣẹ.—Ka Oníwàásù 5:4, 5.
ṢÓ TỌKÀN Ẹ WÁ?
11, 12. (a) Kí ló yẹ kó dá ẹnì kan tó fẹ́ ṣèrìbọmi lójú? (b) Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìrìbọmi wò ó?
11 Bíbélì sọ pé gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà, tó fi mọ́ àwọn ọ̀dọ́, á máa sìn ín “tinútinú.” (Sáàmù 110:3) Torí náà, ó yẹ kó dá ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi lójú pé ó ti ọkàn rẹ̀ wá. Ìyẹn lè gba pé kó o ronú lórí ohun tó o fẹ́ ṣe yìí dáadáa, pàápàá tó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí tó tọ́ ẹ dàgbà.
12 Bó o ṣe ń dàgbà, o lè máa rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣèrìbọmi, lára wọn sì lè jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn àbúrò rẹ tàbí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Àmọ́, ṣọ́ra kó o má lọ bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ìwọ náà gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kìkì nítorí pé àwọn kan ti ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí kó o bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé ìwọ náà kì í
ṣọmọdé mọ́, ó sì yẹ kó o ti ṣèrìbọmi. Kí ló máa mú kó dá ẹ lójú pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìrìbọmi ni ìwọ náà fi ń wò ó? Fara balẹ̀ ronú lórí ìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì. Wàá rí ọ̀pọ̀ ìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e.13. Báwo lo ṣe máa mọ̀ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ló tọkàn ẹ wá pé kó o ṣèrìbọmi?
13 Ọ̀nà kan tó o lè gbà mọ̀ tó bá jẹ́ pé ó tọkàn ẹ wá pé kó o ṣèrìbọmi ni pé kó o kíyè sí àdúrà tó ò ń gbà. Ṣé o máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lemọ́lemọ́? Ṣé àdúrà rẹ máa ń ṣe pàtó? Ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ kó o mọ bí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà ṣe lágbára tó. (Sáàmù 25:4) Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àdúrà wa nígbà tá a bá ka Bíbélì. Ọ̀nà míì tó o lè gbà mọ̀ bóyá òótọ́ lo fẹ́ sún mọ́ Jèhófà tó sì ti ọkàn ẹ wá láti sìn ín ni pé kó o ṣàyẹ̀wò bí o ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́. (Jóṣúà 1:8) Ó yẹ kó o bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé? Ṣé wọn kì í fipá mú mi tó bá di pé ká ṣe Ìjọsìn Ìdílé?’ Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ló tọkàn rẹ wá pé kó o ṣèrìbọmi.
KÍ NI ÌYÀSÍMÍMỌ́?
14. Sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi.
14 Àwọn ọ̀dọ́ kan lè má mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Àwọn kan lè sọ pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà àmọ́ àwọn ò tíì ṣe tán láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, ṣé irú ẹ̀ ṣeé ṣe? Ìyàsímímọ́ ni àdúrà tó o gbà láti ṣèlérí fún Jèhófà pé wàá máa sìn ín títí láé. Tó o bá wá ṣèrìbọmi làwọn èèyàn á tó mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Torí náà, kó o tó ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
15. Kí ni ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí?
15 Nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o sọ fún un pé o ti di tiẹ̀ báyìí. O ṣèlérí pé ìjọsìn Ọlọ́run ni nǹkan tó máa ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ. (Ka Mátíù 16:24.) Ìlérí tó o bá Ọlọ́run ṣe yìí kì í ṣe ohun tó yẹ kó o fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. (Mátíù 5:33) Báwo wá lo ṣe máa fi hàn pé o ti gbà pé o kì í ṣe ti ara rẹ mọ́ àti pé ti Jèhófà lo jẹ́ báyìí?—Róòmù 14:8.
16, 17. (a) Ṣàpèjúwe ohun tó túmọ̀ sí láti sẹ́ ara rẹ. (b) Kí ni ẹni tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ ń sọ ní ti gidi?
16 Ẹ jẹ́ ká ronú lórí àpẹẹrẹ kan. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan fi mọ́tò kan ta ẹ́ lọ́rẹ. Ó kó àwọn ìwé mọ́tò náà fún ẹ, ó wá sọ pé: “Mọ́tò yìí ti di tìẹ.” Àmọ́, ó wá fi kún un pé: “Ọwọ́ mi ni kọ́kọ́rọ́ mọ́tò náà máa wà. Èmi ni màá sì máa wà á, kì í ṣe ìwọ.” Ojú wo lo máa fi wo ẹ̀bùn tí ọ̀rẹ́ rẹ fún ẹ yìí? Ǹjẹ́ inú rẹ á dùn sí ọ̀rẹ́ rẹ yìí?
17 Tẹ́nì kan bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tó ń sọ fún Ọlọ́run ni pé: “Mo ti fi ayé mi fún ọ. Tìẹ ni mo jẹ́.” Ó lẹ́tọ̀ọ́ kí Jèhófà retí pé kí onítọ̀hún mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, tẹ́ni náà bá wá lọ ń yọ́ ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́, tó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà ńkọ́? Àbí tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ gba iṣẹ́ tó máa gba gbogbo àkókò tó Jòhánù 6:38.
yẹ kó lò lóde ẹ̀rí tàbí tó ń jẹ́ kó pa ìpàdé jẹ lọ́pọ̀ ìgbà ńkọ́? Ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ò mú ìlérí tó ṣe fún Jèhófà ṣẹ nìyẹn. Ṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tó di kọ́kọ́rọ́ mọ́tò mọ́wọ́. Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sọ fún un pé, “Mo ti fi ìgbésí ayé mi fún ọ, kì í tún ṣe tèmi mọ́.” Torí náà, ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe la ó máa ṣe kódà kó jẹ́ ohun tí kò wù wá ṣe. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—18, 19. (a) Báwo ni ohun tí Rose àti Christopher sọ ṣe fi hàn pé téèyàn bá ṣèrìbọmi, ó máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà? (b) Báwo ni àǹfààní tá a ní láti ṣèrìbọmi ṣe rí lára rẹ?
18 Ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ tó gba àròjinlẹ̀ ni ìrìbọmi. Àǹfààní tí ò lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ láti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ká sì ṣèrìbọmi. Àwọn ọ̀dọ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì lóye ohun tí ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì ti ṣèrìbọmi. Wọn ò kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe. Ọ̀dọ́ kan tó ti ṣèrìbọmi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rose sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò sì sí nǹkan tí mo lè fi ìgbésí ayé mi ṣe tó lè fún mi láyọ̀ bíi kí n máa sin Jèhófà. Nínú gbogbo ìpinnu tí mo ti ṣe nígbèésí ayé mi, mo gbà pé bí mo ṣe pinnu láti ṣèrìbọmi ló ṣì fi mí lọ́kàn balẹ̀ jù lọ.”
19 Christopher tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ńkọ́? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó pinnu pé òun máa ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún méjìlá? Ó sọ pé inú òun dùn gan-an pé òun ṣe irú ìpinnu tóun ṣe yẹn. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], Bẹ́tẹ́lì ló sì ti ń sìn báyìí. Ó sọ pé: “Ìrìbọmi tí mo ṣe yẹn náà ló yẹ kí n ṣe. Ohun tí mo láǹfààní láti máa ṣe fún Jèhófà àti ètò rẹ̀ ń fún mi láyọ̀.” Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀? A máa jíròrò ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Ọ̀dọ́ kan tó dàgbà dénú ò ní máa ṣiyè méjì nípa ohun tó gbà gbọ́, kódà nígbà tí nǹkan bá le koko
Ọ̀rọ̀ tó gba àròjinlẹ̀ ni ìrìbọmi, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́