Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àdúrà

Àdúrà

Ǹjẹ́ ẹnì kan tiẹ̀ wà tó ń gbọ́ àdúrà wa?

“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.”​—Sáàmù 65:2.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan sọ pé “ibi téèyàn bá ti gbàdúrà ni àdúrà náà mọ.” Ọ̀pọ̀ àwọn tí ìyà ń jẹ tiẹ̀ máa ń rò pé kò sẹ́ni tó ń gbọ́ àdúrà wọn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; ṣùgbọ́n ojú Jèhófà lòdì sí àwọn tí ń ṣe àwọn ohun búburú.” (1 Pétérù 3:​12) Kò sí àní-àní pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wa. Àmọ́, ó máa ń pe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí àdúrà àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ẹsẹ Bíbélì kan tiẹ̀ sọ pé ó máa ń wu Ọlọ́run láti fetí sí àdúrà wa, ó ní: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:​14) Ẹ ò rí i pé, ó yẹ kéèyàn fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ń gbà ládùúrà, kó lè rí i dájú pé ó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

Báwo ló ṣe yẹ ká gbàdúrà?

“Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.”​—Mátíù 6:7.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ohun tí wọ́n kọ́ àwọn èèyàn nínú ẹ̀sìn Búdà, Kátólíìkì, Híńdù àtàwọn Mùsùlùmí ni pé, wọ́n lè fi ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà tàbí tẹ̀suba ka àwọn ọ̀rọ̀ kan ní àkàtúnkà nígbà tí wọ́n bá ń ṣàdúrà.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àdúrà gbọ́dọ̀ tọkàn wa wá, ká sì fòótọ́ inú sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́sórí tàbí lọ́nà àtúnwí asán. Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe dà bí wọn, nítorí Ọlọ́run tí í ṣe Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.”​—Mátíù 6:​7, 8.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tẹ́nì kan bá ń gbàdúrà lọ́nà tí Ọlọ́run kò fẹ́, ńṣe ló ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò, tí ò bá sì ṣọ́ra, ó lè múnú bí Ọlọ́run. Bíbélì wá kìlọ̀ fún wá pé, àdúrà àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn máa ń kó Ọlọ́run ní “ìríra.”​—Òwe 28:​9, Bíbélì Mímọ́.

Ta ló yẹ ká gbàdúrà sí?

“Ẹ wá Jèhófà [Ọlọ́run], ­nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é ­nígbà tí ó wà nítòsí.”​—Aísáyà 55:6.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn onígbàgbọ́ kan máa ń gbàdúrà sí Màríà tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn míì tí wọ́n kà sí “àwọn ẹni mímọ́.” Lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni “Ẹni Mímọ́” tó ń jẹ́ Anthony ti ìlú Padua tí wọ́n gbà pé ó ń bójú tó “àwọn nǹkan tẹ̀mí àti ohun téèyàn nílò kíákíá.” Bákan náà, “Ẹni Mímọ́” tó ń jẹ́ Jude tí wọ́n gbà pé ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú “àwọn ipò tó ṣòro.” Àwọn tó ń gbàdúrà sí àwọn “ẹni mímọ́” tàbí àwọn áńgẹ́lì máa ń rò pé táwọn bá fi ọlá wọn tọrọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, á mú kó gbọ́ àdúrà àwọn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 6:9) Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”​—Fílípì 4:6.