Ǹjẹ́ Ewu Wà—Nínú Wíwọkọ̀ Òfuurufú?
Ǹjẹ́ Ewu Wà—Nínú Wíwọkọ̀ Òfuurufú?
ÀWỌN kan fipá darí ọkọ̀ òfuurufú akérò ńlá mẹ́rin gba ibòmíràn. Ọkọ̀ òfuurufú mẹ́rin já lulẹ̀. Àwọn ilé àwòṣífìlà táwọn èèyàn ti mọ̀ bí ẹní mowó di èyí tó pa rẹ́ ráúráú. Àwòrán bí ọkọ̀ òfuurufú gbàràmù-gbaramu kan ṣe já wọnú ọ̀kan lára àwọn Ilé Gogoro méjì tí wọ́n ń pè ní Twin Towers nílẹ̀ Amẹ́ríkà tí wọ́n sì rún wómúwómú kò yéé fara hàn lórí tẹlifíṣọ̀n.
Àwọn àjálù tó ṣẹlẹ̀ ní September 11, 2001 ti mú wa wọ sànmánì tuntun kan tó kún fún jìnnìjìnnì, tó jẹ́ pé ńṣe ni àwọn apániláyà wá ń fòòró ẹ̀mí àwọn èèyàn báyìí. Wọ́n ti sọ ọkọ̀ òfuurufú di ohun tí wọ́n ń lò láti fi ṣe iṣẹ́ ibi wọn, àní, ó ti di àdó ikú.
Látàrí èyí, ìbẹ̀rù tuntun ti dé bá àwọn tó ń wọ ọkọ̀ òfuurufú, ìyẹn ni pé: Àwọn tọ́kàn wọn ti máa ń balẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọ́n bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú ti wá di ẹni tí jìnnìjìnnì ń mú, tí ẹ̀rù ń bà wọ́n pé àwọn apániláyà lè lọ wà nínú ọkọ̀ tí àwọn wà nínú rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, onírúurú àwọn jàǹbá ọkọ òfuurufú tó burú jáì tí kò tiẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwọn apániláyà ló ti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àjálù September 11, èyí sì tún ti mú kí ẹ̀rù tó ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn láti wọ ọkọ̀ òfuurufú pọ̀ sí i.
Òótọ́ ni pé àwọn olówó ló ń wọkọ̀ òfuurufú, torí pé àìmọye èèyàn kárí ayé ni agbára wọn kò lè gbé e. Àmọ́, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ó pọn dandan fún wọn láti máa wọ̀ ọ́ nígbà gbogbo. Kò sọ́gbọ́n tí àwọn èèyàn tí iṣẹ́ wọn ń béèrè pé kí wọ́n máa rìnrìn àjò gan-an lè dá tí wọn ò fi ní wọ ọkọ̀ òfuurufú. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọkọ̀ òfuurufú làwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì àtàwọn Kristẹni òjíṣẹ́ ní láti wọ̀ dé àwọn ibi jíjìnnà tá a yàn fún wọn láti lọ ṣiṣẹ́, òun náà ni wọ́n á sì tún wọ̀ padà. Kódà fún àwọn tó jẹ́ tálákà pàápàá, ọkọ̀ òfuurufú nìkan ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó máa ń wà nígbà míì láti rìnrìn àjò tí ìṣòro ìlera bá ṣàdéédéé yọjú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn awakọ̀ òfuurufú àtàwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ ló sì wà tó jẹ́ pé fífò lójú sánmà ni iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn.
Kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń rìnrìn àjò nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú tó kúrò nílé, wọ́n ní láti fi aya, ọkọ, àtàwọn ọmọ wọn tẹ́rù ń bà lọ́kàn balẹ̀, ẹ̀rù sì lè máa ba àwọn fúnra wọn pàápàá. Bí ìrìn-àjò tí kò jẹ́ nǹkan kan tẹ́lẹ̀ rí sí àwọn èèyàn tó ń wọkọ̀ òfuurufú ṣe wá ń di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ báyìí, wọ́n ti wá ń rò ó wò bóyá ó ṣì bọ́gbọ́n mu láti máa wọ ọkọ̀ òfuurufú.
Láti gbé àwọn ohun tó ń kọni lóminú yìí yẹ̀ wò, àwọn oníròyìn ìwé ìròyìn Jí! kàn sí àwọn ògbógi nínú ọ̀ràn ààbò, àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfuurufú, àwọn lọ́gàá-lọ́gàá nídìí iṣẹ́ ìrìn-àjò ọkọ̀ òfuurufú, àtàwọn tó máa ń tún ọkọ̀ òfuurufú ṣe. Ó jọ pé gbogbo wọn fara mọ́ kókó kan, ìyẹn ni pé: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ òfuurufú ṣì jẹ́ ọkàn lára àwọn ọ̀nà tó fọkàn ẹni balẹ̀ jù lọ láti rìnrìn àjò, síbẹ̀, àwọn ewu tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú báyìí ń béèrè fún àwọn ìgbésẹ̀ tuntun, kí ààbò lè túbọ̀ wà fún àwọn arìnrìn àjò.
Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ìṣòro tó wà nínú ìrìn àjò nípasẹ̀ ọkọ òfuurufú àti ohun tí ìwọ bí ẹnì kan lè ṣe láti mú ààbò rẹ gbópọn sí i, kí ara sì lè túbọ̀ rọ̀ ọ́ tó o bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú.