ÌBÉÈRÈ 11
Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Sí Ẹni Tó Bá Kú?
“Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀; ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.”
“Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn máa kú, àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá . . . Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú, ibi tí ìwọ ń lọ.”
“[Jésù] fi kún un pé: ‘Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn, àmọ́ mò ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ kí n lè jí i.’ Àmọ́, ọ̀rọ̀ ikú rẹ̀ ni Jésù ń sọ. Wọ́n rò pé ó sọ pé ó ń sùn kó lè sinmi. Jésù wá sọ fún wọn ní tààràtà pé: ‘Lásárù ti kú.’”