Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 124

Júdásì Da Jésù, Wọ́n sì Fàṣẹ Ọba Mú Jésù

Júdásì Da Jésù, Wọ́n sì Fàṣẹ Ọba Mú Jésù

MÁTÍÙ 26:47-56 MÁÀKÙ 14:43-52 LÚÙKÙ 22:47-53 JÒHÁNÙ 18:2-12

  • JÚDÁSÌ DALẸ̀ JÉSÙ NÍNÚ ỌGBÀ GẸ́TÍSÉMÁNÌ

  • PÉTÉRÙ GÉ ETÍ ỌKÙNRIN KAN DÀ NÙ

  • WỌ́N MÚ JÉSÙ

Ní báyìí, àwọn àlùfáà ti gbà láti san ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà fún Júdásì kó lè fa Jésù lé wọn lọ́wọ́. Ni Júdásì bá kó ọ̀pọ̀ àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí lẹ́yìn, wọ́n ń wá Jésù lọ láàárín òru. Àwọn ọmọ ogun Róòmù àti ọ̀gágun wọn sì ń tẹ̀ lé wọn.

Ó ṣe kedere pé nígbà tí Jésù ní kí Júdásì kúrò níbi tí wọ́n ti ń jẹ Ìrékọjá, ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà ló lọ. (Jòhánù 13:27) Wọ́n wá kó àwọn aláṣẹ àtàwọn ọmọ ogun jọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé yàrá tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ni Júdásì kọ́kọ́ mú wọn lọ. Àmọ́ ní báyìí, torí pé wọn ò rí Jésù níbẹ̀, Júdásì àtàwọn tó ń tẹ̀ lé e sọdá Àfonífojì Kídírónì, wọ́n sì forí lé ọgbà Gẹ́tísémánì. Ohun ìjà nìkan kọ́ ló wà lọ́wọ́ wọn, wọ́n tún gbé iná dání, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí Jésù mú.

Bí Júdásì àtàwọn tó ń tẹ̀ lé e ṣe ń gun Òkè Ólífì, ọkàn Júdásì balẹ̀ pé òun mọ ibi tí Jésù máa wà. Torí láàárín ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ìgbà yẹn, tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá ń lọ láti Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sábà máa ń dúró ní ọgbà Gẹ́tísémánì. Àmọ́ ilẹ̀ ti ṣú báyìí, ó sì ṣeé ṣe kí òjìji àwọn igi ólífì tó wà nínú ọgbà yẹn ti mú kí ibi tí Jésù wà ṣókùnkùn. Torí náà, ó lè má rọrùn fáwọn ọmọ ogun yẹn láti dá Jésù mọ̀. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n má rí Jésù rí. Ó dájú pé Júdásì máa ní láti ṣe nǹkan kan kí wọ́n lè dá Jésù mọ̀. Ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un, kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ bí ẹ ṣe ń mú un lọ.”—Máàkù 14:44.

Bí Júdásì ṣe mú àwọn tó ń tẹ̀ lé e wọnú ọgbà náà ló rí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù, ó wá lọ bá Jésù. Ó sọ pé: “Mo kí ọ o, Rábì!” ó sì rọra fẹnu ko Jésù lẹ́nu. Jésù bi í pé: “Ọ̀gbẹ́ni, kí lo wá ṣe níbí?” (Mátíù 26:49, 50) Jésù fúnra rẹ̀ ló tún dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Júdásì, ṣé o fẹ́ fi ẹnu ko Ọmọ èèyàn lẹ́nu kí o lè dalẹ̀ rẹ̀ ni?” (Lúùkù 22:48) Àmọ́ o, Júdásì ti ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, torí náà Jésù ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rẹ̀ mọ́!

Jésù wá bọ́ síbi tí ìmọ́lẹ̀ wà, ó sì bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Lára àwọn tó tẹ̀ lé Júdásì sọ pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Jésù fìgboyà sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” (Jòhánù 18:4, 5) Bí Jésù ṣe fìgboyà dáhùn ya àwọn ọkùnrin yìí lẹ́nu, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.

Dípò tí Jésù ì bá fìyẹn sá mọ́ wọn lọ́wọ́, ṣe ló tún bi wọ́n pé ta ni wọ́n ń wá. Wọ́n ní, “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Jésù wá fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn, ó ní: “Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Torí náà, tó bá jẹ́ èmi lẹ̀ ń wá, ẹ fi àwọn yìí sílẹ̀.” Kódà lásìkò tó gbẹgẹ́ yìí, Jésù ò gbàgbé ohun tó ti sọ tẹ́lẹ̀, pé òun ò ní pàdánù ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòhánù 6:39; 17:12) Jésù ti dáàbò bo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, kò sì pàdánù ìkankan nínú wọn, àfi Júdásì “ọmọ ìparun.” (Jòhánù 18:7-9) Ìdí nìyẹn tó fi sọ fáwọn tó wá mú un pé kí wọ́n má fọwọ́ kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó jẹ́ olóòótọ́.

Báwọn ọmọ ogun yẹn ṣe dìde, tí wọ́n ń sún mọ́ Jésù làwọn àpọ́sítélì ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé wọ́n ti fẹ́ mú Jésù lóòótọ́. Ni wọ́n bá bi í pé: “Olúwa, ṣé ká fi idà bá wọn jà?” (Lúùkù 22:49) Kí Jésù tó dá wọn lóhùn, Pétérù ti fa ọ̀kan lára idà méjì tó wà lọ́wọ́ wọn yọ. Ó kọjú sí Málíkọ́sì tó jẹ́ ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.

Jésù wá fọwọ́ kan etí Málíkọ́sì, ó sì wò ó sàn. Ó fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan, ó wá pàṣẹ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.” Jésù ò sá kí wọ́n má bàa mú òun, torí ó sọ pé: “Báwo ni Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ báyìí ṣe máa ṣẹ?” (Mátíù 26:52, 54) Ó wá fi kún un pé: “Ṣé kò yẹ kí n mu ife tí Baba fún mi ni?” (Jòhánù 18:11) Jésù fẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí òun, kódà, kò kọ̀ kí ẹ̀mí òun lọ sí i.

Jésù wá bi àwọn tó wá mú un pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè? Ojoojúmọ́ ni mò ń jókòó nínú tẹ́ńpìlì, tí mò ń kọ́ni, àmọ́ ẹ ò mú mi. Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ lè ṣẹ.”—Mátíù 26:55, 56.

Làwọn ọmọ ogun yẹn, ọ̀gágun wọn àtàwọn aláṣẹ àwọn Júù bá mú Jésù, wọ́n sì dè é. Bí àwọn àpọ́sítélì ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ṣe ni wọ́n fẹsẹ̀ fẹ. Àmọ́ “ọ̀dọ́kùnrin kan” dúró sáàárín àwọn èèyàn náà kó lè tẹ̀ lé Jésù bí wọ́n ṣe ń mú un lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń jẹ́ Máàkù ni ọ̀dọ́kùnrin yìí. (Máàkù 14:51) Nígbà tó yá, àwọn èèyàn yẹn dá ojú rẹ̀ mọ̀ pé ó wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n sì fẹ́ mú un. Nígbà tí wọ́n fẹ́ gba á mú, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó wọ̀ sílẹ̀ sọ́wọ́ wọn, ó sì sá lọ.